13 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Lónìí tàbí lọ́la, a máa rìnrìn àjò lọ sí ìlú yìí, a máa lo ọdún kan níbẹ̀, a máa ṣòwò, a sì máa jèrè,”+ 14 bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.+ Torí ìkùukùu ni yín, tó máa ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.+