10 Nábálì dá àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì lóhùn pé: “Ta ni Dáfídì, ta sì ni ọmọ Jésè? Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ló ń sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn.+ 11 Ṣé oúnjẹ mi àti omi mi àti ẹran tí mo pa fún àwọn tó ń bá mi rẹ́ irun àgùntàn ni kí n wá fún àwọn ọkùnrin tí mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”