Òwe 10:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe ò ní ṣàì wáyé,+Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ á máa fi ọgbọ́n hùwà.+ Òwe 15:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere,+Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń tú ọ̀rọ̀ ẹ̀gọ̀ jáde.