-
1 Àwọn Ọba 4:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra.
-