1 Àwọn Ọba 9:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Ní àkókò yẹn, Hírámù fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà+ ránṣẹ́ sí ọba. 1 Àwọn Ọba 9:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì. 1 Àwọn Ọba 10:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà àti òróró básámù+ tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.+ Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì. 2 Kíróníkà 1:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+
28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.
10 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà àti òróró básámù+ tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.+ Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.
15 Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+