7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.
18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+