-
1 Sámúẹ́lì 30:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Wọ́n rí ọkùnrin ará Íjíbítì kan nínú pápá, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dáfídì. Wọ́n fún un ní oúnjẹ jẹ, wọ́n sì fún un ní omi mu, 12 wọ́n tún fún un ní ègé ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ méjì. Lẹ́yìn tó jẹun tán, okun rẹ̀ pa dà,* torí kò tíì jẹ oúnjẹ kankan tàbí kó fẹnu kan omi láti ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta sẹ́yìn.
-