-
Ẹ́kísódù 30:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn 24 àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n kaṣíà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ pẹ̀lú òróró ólífì tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan.
-
-
Ẹ́kísódù 30:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú àwọn lọ́fínńdà yìí ní ìwọ̀n kan náà:+ àwọn ẹ̀kán sítákítè, ọ́níkà, gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí.
-