9 Ẹ rántí àwọn nǹkan àtijọ́ tó ti wà tipẹ́,
Pé èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíì,
Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹni tó dà bí èmi.+
10 Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀,
Tipẹ́tipẹ́ ni mo sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.+
Mo sọ pé, ‘Ìpinnu mi máa dúró,+
Màá sì ṣe ohunkóhun tó bá wù mí.’+