29 Wàá máa táràrà kiri ní ọ̀sán gangan, bí afọ́jú ṣe máa ń táràrà torí ó wà lókùnkùn,+ o ò sì ní ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe; wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa jà ọ́ lólè léraléra, kò ní sẹ́ni tó máa gbà ọ́ sílẹ̀.+
52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+