ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 20:4, 5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀.+ 5 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,

  • Léfítíkù 26:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n òrìṣà fún ara yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gbé ère òkúta+ tí ẹ gbẹ́ sí ilẹ̀ yín láti forí balẹ̀ fún un;+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.

  • Hábákúkù 2:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Kí ni àǹfààní ère,

      Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?

      Kí ni àǹfààní ère onírin* àti olùkọ́ èké,

      Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,

      Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+

      19 O gbé, ìwọ tí ò ń sọ fún igi pé: “Dìde!”

      Tàbí fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀ pé: “Gbéra nílẹ̀! Máa kọ́ wa!”

      Wò ó! Wúrà àti fàdákà ni wọ́n fi bò ó,+

      Kò sì sí èémí kankan nínú rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́