ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 23:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú,* ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.+

  • Àìsáyà 55:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,

      Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,

      Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ,

      11 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde máa rí.*+

      Kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ,+

      Àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí,*+

      Ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.

  • Sekaráyà 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Àmọ́ ohun tí mo sọ àti àṣẹ tí mo pa fún àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì, ó ṣẹ sí àwọn baba yín lára, àbí kò ṣẹ?’+ Torí náà, wọ́n pa dà sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì sọ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti fi ìyà jẹ wá nítorí àwọn ọ̀nà wa àti àwọn ìṣe wa, bó ṣe pinnu láti ṣe.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́