8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìnírònú àti òmùgọ̀.+
Ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ igi jẹ́ kìkìdá ẹ̀tàn.+
9 Àwọn fàdákà pẹlẹbẹ tí wọ́n kó wá láti Táṣíṣì+ àti wúrà láti Úfásì,
Ohun tí oníṣẹ́ ọnà ṣe àti ohun tí oníṣẹ́ irin ṣe.
Aṣọ wọn jẹ́ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti òwú aláwọ̀ pọ́pù.
Gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀jáfáfá.