-
Dáníẹ́lì 5:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Àmọ́ ìwọ Bẹliṣásárì ọmọ rẹ̀, o ò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí o tiẹ̀ mọ gbogbo èyí. 23 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lo gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run,+ o sì ní kí wọ́n kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ wá fún ọ.+ Ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ pàtàkì, àwọn wáhàrì rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ onípò kejì wá fi wọ́n mu wáìnì, ẹ sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà, wúrà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe, àwọn ọlọ́run tí kò rí nǹkan kan, tí wọn ò gbọ́ nǹkan kan, tí wọn ò sì mọ nǹkan kan.+ Àmọ́ o ò yin Ọlọ́run tí èémí rẹ+ àti gbogbo ọ̀nà rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀.
-