2 Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,+
Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,
Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,
Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+
Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,
Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?