-
Jẹ́nẹ́sísì 46:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì fi kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ gbé Jékọ́bù bàbá wọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ìyàwó wọn. 6 Wọ́n kó agbo ẹran wọn àti ẹrù wọn dání, èyí tí wọ́n ti ní nílẹ̀ Kénáánì. Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ wá dé sí ilẹ̀ Íjíbítì. 7 Ó kó àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin dání wá sí Íjíbítì, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lóbìnrin. Gbogbo ọmọ rẹ̀ ló kó wá.
-