-
Léfítíkù 10:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Àwọn tó sún mọ́ mi+ yóò mọ̀ pé mímọ́ ni mí, wọ́n á sì yìn mí lógo níṣojú gbogbo èèyàn.’” Áárónì sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.
-
-
Ẹ́sírà 1:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+
-
-
Ẹ́sírà 8:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kó fàdákà àti wúrà pẹ̀lú àwọn nǹkan èlò tí mo wọ̀n fún wọn, kí wọ́n lè kó wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerúsálẹ́mù.
-