17 Àwọn ọmọ rẹ pa dà kíákíá.
Àwọn tó ya ọ́ lulẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
18 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò yí ká.
Gbogbo wọn ń kóra jọ.+
Wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.
“Bó ṣe dájú pé mo wà láàyè,” ni Jèhófà wí,
“O máa wọ gbogbo wọn bí ẹni wọ ohun ọ̀ṣọ́,
O sì máa dè wọ́n mọ́ra bíi ti ìyàwó.