-
Àìsáyà 14:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Torí Jèhófà máa ṣàánú Jékọ́bù,+ ó sì máa tún Ísírẹ́lì yàn.+ Ó máa mú kí wọ́n gbé* ní ilẹ̀ wọn,+ àwọn àjèjì máa dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì máa sọ ara wọn di ará ilé Jékọ́bù.+ 2 Àwọn èèyàn máa mú wọn, wọ́n á mú wọn wá sí àyè wọn, ilé Ísírẹ́lì sì máa fi wọ́n ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin+ ní ilẹ̀ Jèhófà; wọ́n máa mú àwọn tó mú wọn lẹ́rú, wọ́n sì máa di olórí àwọn tó fipá kó wọn ṣiṣẹ́.
-