9 Lọ sórí òkè tó ga,
Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Síónì.+
Gbé ohùn rẹ sókè tagbáratagbára,
Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Jerúsálẹ́mù.
Gbé e sókè, má bẹ̀rù.
Kéde fún àwọn ìlú Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+
10 Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa wá tagbáratagbára,
Apá rẹ̀ sì máa bá a ṣàkóso.+
Wò ó! Èrè rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,
Ẹ̀san rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.+