-
Àìsáyà 2:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,
Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+
Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,
A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+
Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,
Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,
Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+
-
-
Àìsáyà 11:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+
Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́,
Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+
Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun,
Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀.
Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+
8 Ọmọ ẹnu ọmú máa ṣeré lórí ihò ṣèbé,
Ọmọ tí wọ́n ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ sì máa fọwọ́ sí ihò ejò olóró.
-