-
Àìsáyà 65:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa jẹun, àmọ́ ebi máa pa ẹ̀yin.+
Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa mu,+ àmọ́ òùngbẹ máa gbẹ ẹ̀yin.
Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa yọ̀,+ àmọ́ ojú máa ti ẹ̀yin.+
14 Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa kígbe ayọ̀ torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn,
Àmọ́ ẹ̀yin máa ké jáde torí ìrora ọkàn,
Ẹ sì máa pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ ọkàn.
-
-
Jeremáyà 17:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Jèhófà, ìwọ ni ìrètí Ísírẹ́lì,
Ojú máa ti gbogbo àwọn tó bá fi ọ́ sílẹ̀.
-
-
Jeremáyà 17:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+
Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.
Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá wọn,
Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá mi.
-