-
Diutarónómì 13:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “Tí ẹnì kan bá di wòlíì tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àlá sọ tẹ́lẹ̀ láàárín rẹ, tó sì fún ọ ní àmì tàbí tó sọ ohun kan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fún ọ, 2 tí àmì náà tàbí ohun tó sọ fún ọ sì ṣẹ, tó wá ń sọ pé, ‘Jẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì,’ àwọn ọlọ́run tí o kò mọ̀, ‘sì jẹ́ ká máa sìn wọ́n,’ 3 o ò gbọ́dọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn tàbí ti alálàá yẹn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń dán yín wò+ kó lè mọ̀ bóyá ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
-