25 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ̀,
Ó sì máa na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí wọn, ó máa lù wọ́n.+
Àwọn òkè máa mì tìtì,
Òkú wọn sì máa dà bí ààtàn lójú ọ̀nà.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.