-
2 Kíróníkà 19:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe láti fi hàn pé ẹ bẹ̀rù Jèhófà nìyí, kí ẹ sì ṣe é pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti gbogbo ọkàn yín:* 10 Nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá wá láti ìlú wọn, tí wọ́n gbé ẹjọ́ tó jẹ mọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ìbéèrè nípa òfin, àṣẹ, àwọn ìlànà tàbí àwọn ìdájọ́ wá, kí ẹ kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má bàa jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìbínú rẹ̀ máa wá sórí ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín. Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí kí ẹ má bàa jẹ̀bi.
-