ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 23:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

      “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+

      Wọ́n ń tàn yín ni.*

      Ìran tó wá láti inú ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ,+

      Kì í ṣe láti ẹnu Jèhófà.+

      17 Léraléra ni wọ́n ń sọ fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún mi pé,

      ‘Jèhófà ti sọ pé: “Ẹ máa ní àlàáfíà.”’+

      Wọ́n sì ń sọ fún gbogbo ẹni tó ní agídí ọkàn pé,

      ‘Àjálù kankan kò ní bá yín.’+

  • Ìsíkíẹ́lì 13:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ṣebí ìran èké lẹ rí, àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ lẹ sì sọ nígbà tí ẹ sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni pé,’ tó sì jẹ́ pé mi ò sọ nǹkan kan?”’

  • Míkà 2:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Bí èèyàn kan bá wà tó ń lépa asán, tó ń tanni jẹ, tó sì ń parọ́ pé:

      “Màá wàásù fún yín nípa wáìnì àti ọtí,”

      Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan-an ni oníwàásù táwọn èèyàn yìí fẹ́!+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́