-
Diutarónómì 17:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ. 16 Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ní kí àwọn èèyàn náà pa dà lọ sí Íjíbítì láti lọ kó ẹṣin sí i wá,+ torí Jèhófà ti sọ fún yín pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún forí lé ọ̀nà yìí mọ́.’
-