28 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó fi irin ṣe ère+ àwọn Báálì.