29 Nígbà ayé Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà kógun wọ Íjónì, Ebẹli-bẹti-máákà,+ Jánóà, Kédéṣì,+ Hásórì, Gílíádì+ àti Gálílì, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì gbà á, ó wá kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+
8 Áhásì wá kó fàdákà àti wúrà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà.+9 Ọba Ásíríà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó lọ sí Damásíkù, ó sì gbà á, ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Kírì,+ ó sì pa Résínì.+
26 Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi èrò kan sọ́kàn* Púlì ọba Ásíríà+ (ìyẹn, Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà), tí ó fi kó àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn, ó kó wọn wá sí Hálà, Hábórì, Hárà àti odò Gósánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.