-
2 Àwọn Ọba 19:29-31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “‘Ohun tó máa jẹ́ àmì fún ọ* nìyí: Lọ́dún yìí, ẹ ó jẹ ohun tó lalẹ̀ hù;* ní ọdún kejì, ọkà tó hù látinú ìyẹn ni ẹ ó jẹ;+ àmọ́ ní ọdún kẹta, ẹ ó fúnrúgbìn, ẹ ó sì kórè, ẹ ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ẹ ó sì jẹ èso wọn.+ 30 Ìyókù àwọn ará ilé Júdà tó sá àsálà máa ta gbòǹgbò nísàlẹ̀,+ wọ́n á sì so èso lókè. 31 Nítorí àṣẹ́kù kan máa jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, àwọn tó là á já sì máa jáde wá láti Òkè Síónì. Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.+
-