-
2 Àwọn Ọba 20:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+ 2 Ni ó bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: 3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ, ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.”+ Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.
-