-
2 Àwọn Ọba 20:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àìsáyà kò tíì dé àgbàlá àárín nígbà tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ pé:+ 5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà aṣáájú àwọn èèyàn mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá mú ọ lára dá.+ Ní ọ̀túnla, wàá lọ sí ilé Jèhófà.+ 6 Màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ, màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà,+ màá sì gbèjà ìlú yìí nítorí orúkọ mi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+
-