ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 1:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Alágídí ni àwọn ìjòyè rẹ, àwọn àtàwọn olè jọ ń ṣiṣẹ́.+

      Gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.+

      Wọn kì í dá ẹjọ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* bó ṣe tọ́,

      Ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.+

  • Jeremáyà 5:26-28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Nítorí àwọn èèyàn burúkú wà láàárín àwọn èèyàn mi.

      Wọ́n ń wò bí àwọn pẹyẹpẹyẹ tó lúgọ.

      Wọ́n ń dẹ pańpẹ́ ikú.

      Èèyàn ni wọ́n ń mú.

      27 Bí àgò tí ẹyẹ kún inú rẹ̀,

      Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tàn kún ilé wọn.+

      Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi di alágbára tí wọ́n sì lọ́rọ̀.

      28 Wọ́n ti sanra, ara wọn sì ń dán;

      Iṣẹ́ ibi kún ọwọ́ wọn fọ́fọ́.

      Wọn kò gba ẹjọ́ ọmọ aláìníbaba rò,+

      Kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí;

      Wọ́n ò fi òdodo dá ẹjọ́ àwọn aláìní.’”+

  • Míkà 2:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Àwọn tó ń gbìmọ̀ ìkà gbé,

      Tí wọ́n ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn!

      Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n gbèrò,

      Torí pé agbára wọn ká a.+

       2 Oko olóko wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n sì gbà á;+

      Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gba ilé onílé;

      Wọ́n fi jìbìtì gba ilé mọ́ onílé lọ́wọ́,+

      Wọ́n gba ogún lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.

  • Míkà 6:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ṣé àwọn ìṣúra tí wọ́n fi ìwà ìkà kó jọ ṣì wà nílé ẹni burúkú

      Àti òṣùwọ̀n eéfà* tí kò péye tó ń ríni lára?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́