-
Jóṣúà 4:21-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Lọ́jọ́ iwájú, tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ àwọn bàbá wọn pé, ‘Kí ni àwọn òkúta yìí wà fún?’+ 22 kí ẹ ṣàlàyé fún àwọn ọmọ yín pé: ‘Orí ilẹ̀ gbígbẹ ni Ísírẹ́lì gbà sọdá Jọ́dánì+ 23 nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run yín mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú wọn títí wọ́n fi sọdá, bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe sí Òkun Pupa nígbà tó mú kó gbẹ níwájú wa títí a fi sọdá.+ 24 Ó ṣe èyí, kí gbogbo aráyé lè mọ bí ọwọ́ Jèhófà ṣe lágbára tó,+ kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.’”
-