-
2 Àwọn Ọba 20:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Lẹ́yìn náà, wòlíì Àìsáyà wá sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ọkùnrin yìí sọ, ibo ni wọ́n sì ti wá?” Torí náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ilẹ̀ tó jìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.”+ 15 Ó tún béèrè pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé* rẹ?” Hẹsikáyà fèsì pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ilé* mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra mi tí mi ò fi hàn wọ́n.”
-