7 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wò ó, mo ti mú kí o dà bí Ọlọ́run fún Fáráò, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ yóò sì di wòlíì rẹ.+ 2 Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ, Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ló máa bá Fáráò sọ̀rọ̀, á sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.