4 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá jẹ́ kí àwọn ohun ìjà tó wà ní ọwọ́ yín dojú kọ yín,* àwọn ohun tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà+ pẹ̀lú àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín lẹ́yìn odi. Màá sì kó wọn jọ sí àárín ìlú yìí.
15 Àmọ́ níkẹyìn, ọba náà ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì, kí wọ́n lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ọmọ ogun púpọ̀.+ Ṣé ó máa ṣàṣeyọrí? Ǹjẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí á bọ́ lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ó lè da májẹ̀mú kó sì mú un jẹ?’+