-
2 Àwọn Ọba 24:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ọba Bábílónì fi Matanáyà àbúrò bàbá Jèhóákínì+ jọba ní ipò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Sedekáyà.+
18 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà láti Líbínà. 19 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+
-