7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá wa ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ gan-an títí di òní yìí;+ tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ni o ṣe fi àwa, àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa lé àwọn ọba ilẹ̀ míì lọ́wọ́, tí wọ́n fi idà pa wá,+ tí wọ́n kó wa lọ sóko ẹrú,+ tí wọ́n kó ohun ìní wa,+ tí wọ́n sì dójú tì wá bó ṣe rí lónìí yìí.+