25 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+ 2 wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà.