-
Jeremáyà 42:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Nígbà náà, gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti Jesanáyà ọmọ Hóṣáyà pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà wá, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, 2 wọ́n sì sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí gbogbo àṣẹ́kù yìí, torí a pọ̀ gan-an tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwa díẹ̀ ló ṣẹ́ kù báyìí,+ bí ìwọ náà ṣe rí i.
-