-
1 Àwọn Ọba 16:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ọdún méjìlá (12) ló sì fi ṣàkóso. Ọdún mẹ́fà ló fi jọba ní Tírísà. 24 Ó ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Ṣémérì ní tálẹ́ńtì* méjì fàdákà, ó kọ́ ìlú kan sórí òkè náà. Ó fi orúkọ Ṣémérì, ẹni tí ó ni* òkè náà pe ìlú tí ó kọ́, ó pè é ní Samáríà.*+
-