-
Jeremáyà 41:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, ìyẹn àwọn tó gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, lẹ́yìn tó ti pa Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin, àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pa dà dé láti Gíbíónì.
-
-
Jeremáyà 42:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Nígbà náà, gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti Jesanáyà ọmọ Hóṣáyà pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà wá, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, 2 wọ́n sì sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí gbogbo àṣẹ́kù yìí, torí a pọ̀ gan-an tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwa díẹ̀ ló ṣẹ́ kù báyìí,+ bí ìwọ náà ṣe rí i. 3 Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sọ ọ̀nà tó yẹ kí a rìn fún wa àti ohun tó yẹ ká ṣe.”
-