24 ‘O mọ òkìtì fún ara rẹ, o sì kọ́ ibi gíga fún ara rẹ ní gbogbo ojúde ìlú. 25 Ibi tó gbàfiyèsí jù ní gbogbo ojú ọ̀nà lo kọ́ àwọn ibi gíga rẹ sí, o sì sọ ẹwà rẹ di ohun ìríra bí o ṣe ń bá gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ṣèṣekúṣe,+ o sì wá jingíri sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó.+