2 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò nípa Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ fún un pé,
‘O dà bí ọmọ kìnnìún tó lágbára ní àwọn orílẹ̀-èdè,
Àmọ́ wọ́n ti pa ọ́ lẹ́nu mọ́.
O dà bí ẹran ńlá inú òkun,+ ò ń jà gùdù nínú odò rẹ,
Ò ń fi ẹsẹ̀ rẹ da omi rú, o sì ń dọ̀tí àwọn odò.’