-
Jeremáyà 25:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Ẹ mu, kí ẹ sì yó, ẹ bì, kí ẹ sì ṣubú, tí ẹ kò fi ní lè dìde+ nítorí idà tí màá rán sáàárín yín.”’ 28 Bí wọn ò bá sì gba ife náà lọ́wọ́ rẹ láti mu ún, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ gbọ́dọ̀ mu ún!
-
-
Ọbadáyà 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Bí o ṣe mu wáìnì lórí òkè mímọ́ mi,
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa mu ìbínú mi nígbà gbogbo.+
Wọn yóò rọ́ ọ sí ọ̀fun, wọn yóò sì gbé e mì,
Yóò sì dà bíi pé wọn kò gbé ayé rí.
-