-
Ọbadáyà 2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;
O ti tẹ́ pátápátá.+
3 Ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,+
Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta,
Ìwọ tó ń gbé ibi gíga, tí o sì ń sọ nínú ọkàn rẹ pé,
‘Ta ló lè rẹ̀ mí wálẹ̀?’
4 Bí o bá tiẹ̀ kọ́lé sí ibi gíga* bí ẹyẹ idì,
Tàbí tí o kọ́ ìtẹ́ rẹ sáàárín àwọn ìràwọ̀,
Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí.
-