-
Ìsíkíẹ́lì 23:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Torí náà, ìwọ Òhólíbà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò ru àwọn olólùfẹ́ rẹ sókè,+ àwọn tí o* kórìíra tí o sì fi sílẹ̀, èmi yóò sì mú kí wọ́n kọjú ìjà sí ọ láti ibi gbogbo,+ 23 àwọn ọmọkùnrin Bábílónì+ àti gbogbo ará Kálídíà,+ àwọn ará Pékódù,+ Ṣóà àti Kóà, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin Ásíríà. Géńdé tó dáa lọ́mọkùnrin ni gbogbo wọn, wọ́n jẹ́ gómìnà àti ìjòyè, jagunjagun àti àwọn tí wọ́n yàn,* gbogbo wọn ń gun ẹṣin.
-