27 “Ẹ gbé àmì kan sókè ní ilẹ̀ náà.+
Ẹ fun ìwo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè lé e lórí.
Ẹ pe àwọn ìjọba Árárátì,+ Mínì àti Áṣíkénásì+ láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ yan agbanisíṣẹ́ ogun láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹṣin gòkè wá bí eéṣú onírun gàn-ùn gàn-ùn.