-
2 Kíróníkà 36:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nebukadinésárì kó lára àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà lọ sí Bábílónì, ó sì kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+
-
-
Ẹ́sírà 1:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+
-
-
Jeremáyà 51:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ó ti gbé mi kalẹ̀ bí òfìfo ìkòkò.
Ó ti gbé mi mì bí ejò ńlá ṣe ń gbé nǹkan mì;+
Ó ti fi àwọn ohun rere mi kún ikùn ara rẹ̀.
Ó ti fi omi ṣàn mí dà nù.
-
-
Dáníẹ́lì 1:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
1 Ní ọdún kẹta àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàgọ́ tì í.+ 2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+
-